Jump to content

Tahmima Anam

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

'Tahmima Anam' (Bẹ̀ngálì: তাহমিমা আনাম; tí a bí ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹwàá, ọdún 1975) jẹ́ akọ̀wé, onkòwé ìtàn àti ìròyìn tí a bí sílú Bangladeshi tó sì dàgbà ni Brítíṣì.[1] Ìwé ìtàn rẹ̀ àkọ́kọ́, A Golden Age (ọdún 2007), ni ó gba àmì ẹ̀yẹ Best First Book ti ọdún 2008 Commonwealth Writers' Prizes. Ìwé ìtàn rẹ̀ tó kọ tẹ̀le , The Good Muslim, ni wọ́n yàn ní ọdún 2011 fún àmì ẹ̀yẹ Man Asian Literary Prize [2] Ó jẹ́ ọmọ ọmọ Abul Mansur Ahmed, ó sì jẹ́ ọmọbìnrin Mahfuz Anam.

A bí Anam ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹwàá, ọdún 1975 ni DhakaMahfuz Anam àti Shaheen Anam. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjì, ó kó lọ sí Paris nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì dara pọ̀ UNESCO láti bá wọn ṣiṣẹ́. Ó dàgbà ní ìlú Paris, New York àti Bangkok, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ìtàn ogun Bangladesh Liberation lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ tó sọ fún pé òun kọ́ ìjà láti lè bá wọ́n jagun ni ọdún 1971 ṣùgbọ́n East Pakistan ti di òmìnira nígbà náà. Bàbá rẹ̀ kìí ṣe ológun.[3][4][5][6]

Ní ọmọ ọdún mẹ́tadínlógún, ó gba àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọ́wọ́ ilé ìwé gíga fún àwọn olùkọ́ ti Mount Holy òkè, níbẹ̀ ni ó sì ti kàwé gboyè ní ọdún 1997.[5][7] Ó gba ìwé ẹ̀rí tàwọn onímọ̀ nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀dá láti Yunifásítì

Ní oṣù kẹta, ọdún 2007, ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́, A Golden Age, John Murray tẹ̀ jáde. Nípa sẹ̀ àtìlẹ́yìn àwọn òbí rẹ̀, ìgbà ogun òmìnira Bangladesh ni ó fi ṣe ibi ìṣeré inú ìtàn náà. Ìwé náà kópa nínú ìpele tó kẹ́yìn nínú ìdíje Costa First Novel Award. Ìwé ìtàn náà dá lé ọmọbìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rehana Haque nígbà ogun Bangladesh fún òmìnira ní ọdún 1971. Ó ti ṣe iṣẹ́ ìwádìí nípa ogun náà lẹ́yìn tó kàwé gboyè tàn án. Nítorí iṣẹ́ ìwádìí náà, ọdún méjì gbáko ni ó lò ní ìlú Bangladesh tí ó sì ṣe ìfọ̀rọ̀wálẹ́nù fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun tó já nínú ogun náà, tí wọ́n ń pè ní 'shongram fighers'. Ó tún ṣiṣẹ́ lórí ère Tareque àti Catherine Masud èyí tí ó gbajú-gbajà 'Matir Moina' (Ẹyẹ alámọ̀ náà), èyí tó ṣe àfihàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nígbà ogun náà.

Ìwé ìtàn rẹ̀ kejì, The Good Muslim, ni ó tẹ̀ jáde ní ọdún 2011, tí ó jẹ́ ìtàn tó ṣí kejì ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́ A Golden Age ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn ogun. Ó wà lórí àkójọ fún àmì ẹ̀yẹ Man Asian Literary. Ní ọdún 2013, a dárúkọ Anam gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Granta's "Best of Young British Novelists".[8] Ní ọdún 2015, ìtàn kúkúrú tí ó kọ "Garments", ti wíwó ilé Rana Plaza, jẹ́ atìlẹ́yìn fùn ún ni ó tẹ̀ jáde tí ó sì gba àmì ẹ̀yẹ O. Henry Award[9][10] ó sì wà ní àkọ́jọ fún àmì ẹ̀yẹ BBC National Short Story Award.[11] Ní ọdún kan náà, ó di adájọ́ fún àmì ẹ̀yẹ Man Booker International Prize 2016.[12]

Ní ọdún 2016, ìwé ìtàn rẹ̀ The Bones of Grace jẹ́ títẹ̀ jáde nípa ṣẹ ọwọ́ HarperCollins.[13] Lọ́dún tó tẹ̀lé, a yàn án gẹ́gẹ́ bí Fellow of the Royal Society of Literature.[14][15] Lára àyọkà tó kọ ti di títẹ̀ jáde nínú The New York Times, The Guardian àti New Statesman. Nínú àwọn àyọkà yìí Anam ti kọ nípa Bangladesh àti àwọn ìṣòro rẹ̀ tí ń peléke si.[16][17][18]

Ní ọdún 2021, ìwé ìtàn rẹ̀ The Startup Wife di títẹ̀ jáde láti ọwọ́ Canongate Books. A yàn án gẹ́gẹ́ bí 'Ìwé tí ó dára jù lọ ti ọdún 2011' láti ọwọ́ Observer, Stylist, Cosmopolitan, Red àti Daily Mail, ó sì tún wà ní àkójọ fún àmì ẹ̀yẹ Comedy Women in Print Prize ọdún 2022.[19][20][21]

Ní ọdún 2022, Anam sọ̀rọ̀ lórí TEDx talk lábẹ́ àkòrí, "The Power of Holding Silence: Making the Workplace Work for Women".[22] Lọ́dún kan náà, Ìwé tó kọ́kọ́ kọ, A Golden Age, ni wọ́n yàn fún àkójọ ìwé fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́ta ti Olòrì, tí ń ṣe àkọ́jọpọ̀ ìwé àádọ́rin tí wọ́n yàn láti àwọn orílẹ̀ èdè tó wà lábẹ́ Commonwealth láti fi ṣe ayẹyẹ pé ìjọba Olòrì pé ewadun.[23]

Ní ọdún 2010, ó fẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ sáyẹ́ǹsì kan láti ìlú Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Roland O. Lamb, tí ó pàdé ní Harvard University. Àwọn tọkọtaya náà ní ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rumi.[13][24] Wọ́n bí láì pé ọjọ́, ó sì kọ̀ láti jẹun fún ọdún márùn-ún, ìpéníjà tí Anam tí kọ nípa rẹ̀.[25] Titi di ọdún 2011, Anam ń gbé nílú London.[26]

Àwọn Ìwé Rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtàn Kúkúrú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • "Saving the World". Granta (London) (Autumn). 2008. 
  • "Anwar Gets Everything". Granta (London) (Spring). 2013. 
  • "Garments". Freeman's (London) (Fall 2015). 2015. 

Àwọn Ìtọ́kási

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Tahmima Anam: ‘A lot of my feminist rage was born when I read The Bell Jar’". the Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-07-15. Retrieved 2023-01-11. 
  2. "Women – Welcome to British Bangladeshi Power 100". British Bangladeshi Power 100. January 2012. Retrieved 1 May 2012. 
  3. "Tahmima Anam lifts the veil on Bangladesh's ugly truths". The Times. https://www.thetimes.co.uk/article/tahmima-anam-lifts-the-veil-on-bangladeshs-ugly-truths-978wfqd7xms. 
  4. Bergquist, Karin (2007). "Mahfuz Anam". Archived from the original on 3 February 2007. https://web.archive.org/web/20070203100431/http://culturebase.net/artist.php?1271.  Outspoken editor from Bangladesh
  5. 5.0 5.1 Tahmima Anam: ‘I have a complicated relationship with Bangladesh’ The Guardian
  6. "A Daughter of Bangladeshi Revolutionaries Makes Sense of Life After War". The New Yorker. https://www.newyorker.com/books/page-turner/tahmima-anam-trilogy-of-life-after-war-in-bangladesh. 
  7. "Tahmima Anam '97 Makes Granta's "Best of Young British Novelists" List". Mount Holyoke College. 
  8. "The Best of Young British Novelists" (PDF). Granta. 
  9. Tahmima Anam Wins O Henry Award The Daily Star
  10. The O. Henry Prize Stories 2017 - Winning Stories O. Henry Prize
  11. BBC National Short Story Award BBC Radio 4
  12. The Man Booker International Prize 2016: Judging Panel Announced The Man Booker Prize
  13. 13.0 13.1 "Tahmima Anam Completes Her 'Bangladesh Trilogy' with The Bones of Grace". The Telegraph. Kolkota. Archived from the original on 19 January 2018.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  14. Natasha Onwuemezi, "Rankin, McDermid and Levy named new RSL fellows", The Bookseller, 7 June 2017.
  15. "Current RSL Fellows". Royal Society of Literature. Archived from the original on 6 February 2019. Retrieved 10 June 2017. 
  16. "A Burst of Energy in Bangladesh". The New York Times. https://www.nytimes.com/2016/04/28/opinion/a-burst-of-energy-in-bangladesh.html?rref=collection%2Ftimestopic%2FAnam%2C%20Tahmima. 
  17. "Is Bangladesh turning fundamentalist?' – and other questions I no longer wish to answer". The Guardian. https://www.theguardian.com/world/2016/may/16/bangladesh-killings-atheist-gay-liberal-isis-tahmima-anam. 
  18. "Bangladesh: Give me back my country". New Statesman. https://www.newstatesman.com/asia/2007/01/bangladesh-bnp-election-vote. 
  19. Anam, Tahmima (2021-06-03). The Startup Wife. https://www.amazon.co.uk/dp/B08NXBJMKD/. 
  20. "Garmus, Ali, Keyes and more longlisted for Comedy Women in Print Prize". The Bookseller (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-15. 
  21. "2022/23 Prize | Comedy Women in Print". CWIP (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-04-05. 
  22. "The power of holding silence: Making the workplace work for women | Tahmima Anam | TEDxManchester - YouTube". www.youtube.com. Retrieved 2022-05-15. 
  23. "The God of Small Things to Shuggie Bain: the Queen's jubilee book list". the Guardian (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-04-18. Retrieved 2022-06-18. 
  24. Hong, Terry (July 2011). "An Interview with Tahmima Anam". Bookslut. http://www.bookslut.com/features/2011_07_017958.php. 
  25. Anam, Tahmima (2019-04-09). "'For five years we dreaded every meal': my infant son's struggle with food" (in en-GB). The Guardian. ISSN 0261-3077. https://www.theguardian.com/society/2019/apr/09/for-five-years-we-dreaded-every-meal-my-infant-sons-struggle-with-food. 
  26. Roy, Amit (5 June 2011). "Eye on England: Good Author". The Telegraph (Kolkota). http://www.telegraphindia.com/1110605/jsp/7days/story_14072500.jsp. 

Àdàkọ:Authority control