Sola Sobowale
Ṣọlá Ṣóbọ̀wálé | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 26 Oṣù Kejìlá 1963 Ìpínlẹ̀ Oǹdó, Nàìjíríà |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ |
|
Parent(s) | Joseph Olagookun, Esther Olagookun |
Ṣọlá Ṣóbọ̀wálé tí wọ́n bí ní ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kejìlá, ọdún 1963, jẹ́ òṣèré sinimá àti adarí eré ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Ó di olókìkí ní ọdún 2001, nínú ìṣàfihàn ti Ìtàn-àkọọ́lẹ̀ Super Story : Oh Father, Oh Daughter.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó dara pọ̀ mọ́ eré orí ìtàgé nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù tí Ẹgbẹ́ Awada Kẹrikẹri ṣe lábẹ́ adarí Adébáyọ̀ Sàlámì . [2] Láàárín ọdún díẹ̀, ó ti ṣe iṣẹ́ akọ̀wé, ìtọ́sọ́nà àti ìgbéjáde ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nàìjíríà. [3] Ó ṣe akọ̀wé, àgbékalẹ̀ ati ìtọ́sọ́nà, Ohun Oko Somida, fíìmù Nàìjíríà kan tí ó jáde ní ọdún 2010 èyí tí ó ṣe ìràwọ̀ Adébáyọ̀ Sàlámì . [4] Ó ṣe ìfihàn nínú Dangerous Twins, fíìmù ti Nàìjírà tí ó jáde ní ọdún 2004 tí Tádé Ògìdán ṣe, ẹni tó kọ fíìmù yìí ni Níji Àkànní . [5] Ó tún ṣe ìfihàn nínú Family on Fire ìṣelọ́pọ̀ ati ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ Tádé Ògìdán . [6]
Ìgbésí Ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Sola Sobowale jẹ́ ìyàwó Dotun Sobowale. Ó bí ọmọ mérin fún ọkọ rẹ̀.[7]
Àwọn àmì ẹ̀yẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 2019, ó gba àmì ẹ̀yẹ African Academy Academy (AMAA) fún Òṣèré tó dára jù lọ fún ipá rẹ̀ ní fíìmù King of Boys tó jáde ní ọdún 2018.
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òṣèré
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Aṣẹ́wó Tó Re Mẹ́kà (1992)
- Diamond Ring (1998)
- Super Story: Oh Father, Oh Daughter (2001).
- Outkast (2001).
- Ayomida (2003)
- Ayomida 2 (2003)
- Dangerous Twins (2004)
- Disoriented Generation (2009)
- Ohun Oko Somida (2010)
- Family on Fire (2011)
- The Wedding Party (2016)
- Christmas Is Coming (2017)
- The Wedding Party 2 (2017)
- King of Boys (2018)
- The Men's Club (2018 - 2020)
- Wives on Strike: The Revolution (2019)
- Gold Statue (2019)
- Shadow Parties (2020)
- In Case of Incasity (2020)
- King of Boys: The Return of the King (2021)
Olóòtú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ayomida (2003)
- Ayomida 2 (2003)
- Ohun Oko Somida (2010)
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "https://punchng.com/entertainment/the-fashionista/ive-lovely-legs-but-i-cant-wear-skimpy-dresses-sola-sobowal". Archived from the original on 2015-01-21. Retrieved 2020-10-03. External link in
|title=
(help) - ↑ http://www.pmnewsnigeria.com/2012/11/30/nigerias-fading-movie-stars/
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2019-10-06. Retrieved 2020-10-03.
- ↑ African Film. https://books.google.com/books?id=2msxBwAAQBAJ&q=Ohun+Oko+Somida+by+sola+sobowale&pg=PA221.
- ↑ http://www.pmnewsnigeria.com/2011/12/05/sola-sobowale-returns-in-family-on-fire/
- ↑ http://www.vanguardngr.com/2012/04/tade-ogidan-plans-to-take-family-on-fire-to-the-people/
- ↑ https://www.thisdaylive.com/