Jump to content

Darulifta-Deoband.com

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Darulifta-Deoband.com
Darulifta-Deoband (website) logo.png
Darulifta-Deoband website (screenshot) 3 February 2022.jpg
Screenshot of homepage on 3 February 2022
URLdarulifta-deoband.com/en/en
Commercial?No
Type of siteIslamic, Hanafi, Legal/Religious
RegistrationRequired
Current statusActive

Darulifta-Deoband.com jẹ́ ojú opó wẹ́ẹ̀bù fatwa èdè méjì  (Urdu àti gẹ̀ẹ́sì) tí àmójútó rẹ̀ jẹ́ láti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Fatwa Darul Uloom Deoband.

Ni ọdun 2016, o jẹ oju opo wẹẹbu fatwa èdè méjì tí ó  tóbi jùlọ ní àgbáyé. wọn fatwa bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún (15,000)ni wọ́n máa ń wò ní Darul Uloom Deoband ni ọdọọdún, èyítí ẹgbẹ̀rún mẹ̀fà sí méje wá lori ayélujára.[1] Ní Oṣù Kiní ọdún 2022, Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-èdè India fun ìdá'bòbo Àwọn ẹ̀tọ́ Ọmọdé ṣe rọ ìjọba láti ti ojú opó wẹ́ẹ̀bù náà, tọ́ka sí àkóónú rẹ̀ bí ìrúfin àwọn òfin orílẹ̀-èdè náà.[2]

Darul Uloom Deoband bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò  àgbékalẹ̀ ojú opó wẹ́ẹ̀bù  wọn ní ọdún 2002 lẹhìn dídé tí àwọn ohun èlò intanẹẹti si àwọn ìlú àti àwọn ìlú ǹlá ní India. Lẹ́yìn ìfilọ́lẹ̀ ojú opó wẹ́ẹ̀bù àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀ imeeli, ẹka ẹ̀kọ́ fatwa Darul Uloom Deoband tabi Darul Ifta bẹ̀rẹ̀ sií dáhùn àwọn ìbéèrè láti gbogbo àgbáyé lori intanẹẹti.

Fún ìdí èyí, nitori ìlọsókè  àwọn ìbéèrè orí ayélujára àti àwọn ìbéèrè èlò miiran, Darul Uloom Deoband ṣe àgbékalẹ̀ Ẹ̀ka Fatwa lórí Ayélujára ní ọdún 2005 àti ojú opó wẹ́ẹ̀bù elédè méjì (Urdu ati Gẹẹsi) tí a ń pè ní Darulifta-Deoband.com tí wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2007. Ní ìgbà tí ó máa di oṣù kejìlá ọdún 2016, ojú opó wẹ́ẹ̀bù náà ni Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n fatwa tí  a ti yàn ní ẹ̀ka àwọn èdè Urdu àti Gẹ̀ẹ́sì, èyí sọọ́ di  ojúlé wẹ́ẹ̀bù elédè méjì tí ó tóbi jùlọ tí a ti lè rí fatwa. Ni Oṣu Kini ọdun 2022, ojú opó wẹ́ẹ̀bù náà ní àwọn fatwa ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án ó lé ọgọ́sàn-án lékan (9,181) ní apákan Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn fatwa ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìléọgbọ̀n lé ẹgbẹ̀rin lé méjìlá (32,812) ní apákan Urdu. Òǹkà awọn mufti ti onìdahun jẹ mẹ́sàn-án, Habibur Rahman Khairabadi ni Olórí wọn.[3]

Bí a bá wo ẹdun kan l'ábẹ́ òfin kẹtàlá, ìpín kiní (j)  (13 (1) (j) )ti Ìdáàbòbò ti Ofin Àwọn ẹ̀tọ́ Ọmọ, Ìgbìmọ̀ ti Orílẹ̀-èdè fún Ìdáàbòbò ti Àwọn ẹ̀tọ́ Ọmọdé (NCPCR) sọ pé àwọn àlàyé àti àwọn ìdáhùn tí wọ́n ń fún àwọn oníbéèrè ní ọjú-ọ̀nà fatwa tí Darul Uloom Deoband kò ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti àwọn ìlànà orílẹ̀-èdè náà. Ìgbìmọ̀ náà sọ pé Irú àwọn àsọyé bẹ́ẹ̀ lòdì sí àwọn ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé àtipé ó ṣe ìpalára fún wọn pẹlú ìgbàláàyè sí Intanẹẹti.

Wọ́n sì rọ Ìjọba ti Uttar Pradesh lati gbésẹ̀lé ìgbàláàyè sí ojú opó wẹ́ẹ̀bù náà títí irú àwọn àkóónú bẹ́ẹ̀ yóò fi kúrò.

Ẹgbẹ Ìsìláámù ti Àwọn ọmọ ilé-ìwé ti India tọ́ka sí èyí bí “ìgbìyànjú mìíràn láti ba ilé-kéhú náà jẹ́.”[4] Abul Qasim Nomani, Gíwà Darul Uloom Deoband sọ ní ìdáhùn sí ẹ̀dùn náà pé, àwọn tí ó wá fatwa ní ọjú-ọ̀nà ti Sharia nìkan ni wọ́n dá lóhùn ni ọjú-ọ̀nà ti Sharia. Kò si ọ̀ranyàn níbẹ̀.

Wọ́n ti ojú opó yìí pa ní ọjọ́ keje, oṣù kejì ọdún 2022.[5]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]