Jump to content

Ògún Lákáayé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ògún)

Ògún nínú ìtàn aròsọ àtẹnu-dẹ́nu ní ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ òrìṣà tó ní agbára lórí ina, irin, ìsọdẹ, ìṣèlú àti ogun.


“Ọmọ ti yóò j’aṣàmú, kékeré ló ti ńjẹnu ṣámúṣámú lọ.” Owe àwọn àgbà yìí ló bá ẹni tí ó kọ ìwé yìí mu ọ̀gbẹ́ni Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀, nitori àkókò ti o ńkẹ́kọ̀ọ́ ni ilé-ìwé àwọn olùkọ́ ti Lúkù Mimọ́ ni ó kọ ìwé yìí, nílùú Ìbàdàn.

Lákòókò yìí, mo ni àǹfàní àti jẹ́ olùkọ́ọ rẹ̀ nínú ẹ̀ka ẹ̀kọ́ Yorùbá, àti láti tún jẹ́ alábòjútó Ẹgbẹ́ Ìjìnlẹ̀ Yorùbá ti Kọ́lẹ́ẹ̀jì náà. Lọ́nà méjèèji yii ni Ọ̀gbẹ́ni Ọládàpọ̀ ti fi ara rẹ̀ hàn bii akọni nínú èdèe Yorùbá. dé ibi pé ni ọdún kẹta rẹ̀ ni Kọ́lẹ́ẹ̀jì, òun ni a fi jẹ alága Ẹgbẹ́ Ìjinlẹ̀ Yorùbá ti Kọ́lẹ́ẹ̀jì náà.

Nígbà tí ó sì dip é ki á máa wá eré ti ẹgbẹ́ yóò ṣe ní ọdún 1967, eré tirẹ̀ yii ni a yàn pé ó gbayì jù nínú gbogbo àwọn eré ti a yẹ̀wò nígbà náà. Àwọn ti ó wo eré náà nígbà ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣe é ni Gbọ̀ngàn Sẹ̀ntínárì ní Aké, Abẹ́òkútà àti ni Gbọ̀ngàn Àpèjọ ti Ilé-Ẹkọ́ giga tí ìlú Ayétòrò ni, “àrímá -leèlọ àwò-padà-sẹ́hin” ni eré náà í-ṣe. Eyi ló fún mi ni ìdùnnú láti lè kọ ọ̀rọ̀ àsọsiwájú yìí lórí ìwé ÒGÚN LÁKÁAYÉ. Eré náà kọ́ ènìyàn ni ògidìi Yorùbá. o fi oriṣiriṣI àṣà Yorùbá hàn; ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó kọ́ ènìyàn lọ́gbọ́n lóríṣiríṣi ọ̀nà.

  • Ọlatunbọsun Ọladapọ (1983) Ògún Lákaayé Ibadan; Onibonoje Press and Book Industries (NIG) LTD. Ojú-iwé 138.