Al-Da'i
Al-Da'i jẹ́ ìwé Lárúbáwá èyí tí wọ́n ń ṣe àtẹ́jáde rẹ̀ lóṣoṣù láti Darul Uloom Deoband, lábẹ́ ìdarí olóòtú Wahiduzzaman Kairanawi ní ọdún 1976.[1][2] Àfojúsùn pàtàkì ti ìwé náà ni àwọn ènìyàn pàtàkì - pátákí ti Darul Uloom Deoband àti àwọn tó ti kàwé gboyè nìkan. Látàrí ìyàtọ̀ rẹ̀, ó ti fa ọkàn àwọn onímọ̀ láti orílẹ̀ èdè India àti Arab world.[3] Abul Qasim Nomani ni ó ṣe àkójọpọ̀ ìwé náà nígbà tí Arif Jameel Mubarakpuri sì jẹ́ olóòtú àgbà. Noor Alam Khalil Amini jẹ̀ olóòtú pàtàkì fún ìwé yìí.
Gbígbà Wole
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Qasim Yusuf al-Shaykh, onímọ̀ ẹ̀sìn Mùsùlùmí kan láti Bahrain, yin ìwé náà, ó sọ wípé, "inú wa dùn púpọ̀ láti kà nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ nínú àwọn ìwé ẹ̀sìn Mùsùlùmí tí ẹ kọ nibi tí a ti rí ẹ̀mí ti Islam àti èrò tí ń lani lọ́yẹ nípa ìgbàgbọ́. Inú wa sì dùn jùlọ nígbà tí a rí àwọn àyọkà nípa Muhammad Tayyib Qasmi, olórí Yunifásítì Mùsùlùmí ní Deoband àti àwọn ẹni pàtàkì mìíràn."[3]
Tún Wo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ìtọ́kási
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Citations
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Àdàkọ:Cite thesis
- ↑ Àdàkọ:Cite thesis
- ↑ 3.0 3.1 Ahmed, Farid Uddin (July 2019). "Arabic Journalism in India: its growth and development". The Echo 8 (1): 312. ISSN 2278-5264. https://www.thecho.in/files/34.-Dr.-Farid-Uddin-Ahmed-15-07-19.pdf.