Jump to content

Tafseer-e-Usmani

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àtúnyẹ̀wò ní 19:09, 2 Oṣù Ọ̀wàrà 2024 l'átọwọ́ Apalopadidun1 (ọ̀rọ̀ | àfikún)
(ìyàtọ̀) ← Àtúnyẹ̀wò tópẹ́ju | Àtúnyẹ̀wò ìsinsìnyí (ìyàtọ̀) | Àtúnyẹ̀wò tótuntunju → (ìyàtọ̀)
Tafseer-e-Usmani
Fáìlì:Cover of Tafseer-e-Usmani.jpg
English cover
Olùkọ̀wé
Àkọlé àkọ́kọ́تفسیر عثمانی , ترجمۂ شیخ الہند
CountryIndia
LanguageUrdu
SubjectTafsir
GenreClassic
Publisher
Media typePrint
ISBNÀdàkọ:ISBNT English
297.1227
LC ClassBP130.4 .U76 2003

Tafseer-e-Usmani tàbí Tarjuma Shaykh al-Hind ( Urdu: تفسیر عثمانی, ترجمۂ شیخ الہند </link> ) jẹ́ ògbufọ̀ Urdu àti ìtumò Al-Qur'an . Ó jẹ́ orúkọ tí wọ́n fi sọrí òǹkọ̀wé àkọ́kọ́, Mahmud Hasan Deobandi, ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ ìtumọ̀ ni 1909. Lẹ́yìn náà niShabbir Ahmad Usmani darapọ̀ mọ́ ọ láti parí àwọn àsọyé. Ìtumọ̀ náà ti ní ìdánimọ̀ àti ìmọrírì láti ọ̀dọ̀ àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n ń sọ ède Urdu nítorí ọnà tí ó ní òye àti ìtumọ̀ ti òye ti ọ̀rọ̀ Al-Qur’an. Ìtumọ̀ Urdu kan ni Ìjọba Saudi Arabia ti tẹ̀ jáde ní ọdún 1989 nípasẹ̀ Ilé-iṣẹ́ Ọba Fahd fún Títẹ̀ Al-Qur’an Mímọ́ , lákòókò tí Ìjọba Bangladesh ti ṣe àtẹ̀jáde ìtumọ̀ Bengali kan ní ọdún-un 1996 nípasẹ̀ Islamic Foundation Bangladesh . [1]

abẹlẹ

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ìtàn àkọ̀ọ́lẹé Tafseer-e-Usmani ṣeéṣe ìtọpasẹ̀ padà sí ìbẹ̀rẹ ọ̀rúndún 20th ní ihà ilẹ̀ India. Iṣẹ́ náà jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ Mahmud Hasan Deobandi, tí ó jẹ́ òpìtan-onímọ̀ àti olùdarí tí ó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ ẹ Deobandi . Mahmud Hasan Deobandi bẹ̀rẹ̀ ṣí ní ṣe ògbufọ̀ Al-Qur'an sí Urdu ní ọdún-un 1909. Lákòókò ìlànà ògbufọ̀ yìí, Mahmud Hasan Deobandi àti díẹ̀ nínu àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ ni wọ́n tì mọ́lé fún ìlọ́wọ́sí i wọn nínu Ẹgbẹ Lẹta Silk, ẹgbẹ́ òṣèlú kan tí ó lòdì sí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì ní India, tí wọ́n sì tì í mọ́ túbú níMalta . Pẹ̀lu bí ó ti wà ní ẹ̀wọ̀n, Mahmud Hasan Deobandi tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ẹ rẹ̀ lóri ìtumọ̀ Al-Qur'an. Ó lo àkókò o rẹ̀ ní Malta láti parí ìtumọ̀ náà, nígbà tó sì fi máa di ọdún 1918, ó ti parí iṣẹ́ náà. Lákòókò ẹ̀wọn rẹ̀, Mahmud Hasan Deobandi tún bẹ̀rẹ kíkọ àwọn àkọsílẹ̀ àlàyé nínu ọ̀rọ̀ náà, tí ó pèsè ọnà àsọyé kan ní ẹ̀gbẹ́ afọ̀ náà. Mahmud Hasan Deobandi kú ní ọjọ́ ọ 18 Rabi al-Awal 1338 (kàlẹ́ndà Islam) ṣááju kí ó tó parí i gbogbo àwọn àsọyé. [2] Ní àkókò ikú u rẹ̀, ó ti parí àwọn àsọyé tiAn-Nisa, tí ó sì fi àwọn iṣẹ́ mìíràn tí kò ì tíì tẹ̀ jáde sílẹ̀. Shabbir Ahmad Usman, òpìtàn-onímọ̀ mìíràn àti ọmọ-lẹ́hìn Mahmud Hasan Deobandi, gba iṣẹ́-ṣíṣe láti tẹ̀síwájú àti láti parí àwọn àsọyé. Usmani mú u lókùn-ún-kúndùn láti parí iṣẹ́ ẹ Tafseer-e-Usmani.

Àwọn ìgbìnyànjú àpapọ̀ ọ Mahmud Hasan Deobandi àti Shabbir Ahmad Usmani yọrí sí ìpárí í Tafseer-e-Usmani, èyí tí ó di mímọ̀ọ bí ìtumọ̀ Urdu àti ìtumọ̀ Al-Qur’an ṣe di pàtàkì. [2]

  1. . Archived on 7 May 2023. Error: If you specify |archivedate=, you must first specify |url=. 
  2. 2.0 2.1 Wani 2012, p. 85.