Mòsámbìkì
Republic of Mozambique República de Moçambique
| |
---|---|
Olùìlú àti ìlú tótóbijùlọ | Maputo |
Àwọn èdè ìṣẹ́ọba | Portuguese |
Vernacular languages | Swahili, Makhuwa, Sena |
Orúkọ aráàlú | Mozambican |
Ìjọba | Republic |
Filipe Nyusi | |
Carlos Agostinho do Rosário | |
Independence | |
• from Portugal | June 25, 1975 |
Ìtóbi | |
• Total | 801,590 km2 (309,500 sq mi) (35th) |
• Omi (%) | 2.2 |
Alábùgbé | |
• 2009 estimate | 22,894,000[1] (54th) |
• 2007 census | 21,397,000 (52nd) |
• Ìdìmọ́ra | 28.7/km2 (74.3/sq mi) (178th) |
GDP (PPP) | 2008 estimate |
• Total | $18.740 billion[2] |
• Per capita | $903[2] |
GDP (nominal) | 2008 estimate |
• Total | $9.897 billion[2] |
• Per capita | $477[2] |
Gini (1996–97) | 39.6 medium |
HDI (2007) | ▲ 0.402 Error: Invalid HDI value · 172nd |
Owóníná | Mozambican metical (Mtn) (MZN) |
Ibi àkókò | UTC+2 (CAT) |
• Ìgbà oru (DST) | UTC+2 (not observed) |
Ojúọ̀nà ọkọ́ | left |
Àmì tẹlifóònù | 258 |
ISO 3166 code | MZ |
Internet TLD | .mz |
|
Mozambique, fun ibise Olominira ile Mozambique (Pọrtugí: Moçambique tabi República de Moçambique, pípè [ʁɛˈpublikɐ di musɐ̃ˈbiki]), je orile-ede ni apaguusuilaorun Africa to ni bode mo Okun India ni ilaorun, Tanzania ni ariwa, Malawi ati Zambia ni ariwaiwoorunt, Zimbabwe ni iwoorun ati Swaziland ati Guusu Afrika ni guusuiwoorun.
Abe Portugal ni Mozambique wa tele. Bèbè gúsù-ìlà-oòrùn Aáfíríkà ni Mozambique wa. Ó tóbi ju Portugal gan-an lọ. Àwọn ìlú tí ó wà ní bèbè Mozambique bíi Laurence Marquis (tí ó jẹ́ olú-ìlú Mozambique) àti Beira ni àwọn ọkọ̀ ojú omi ti ń gúnlẹ̀. Ọkọ̀ ojú irín ni ó so àwọn ìlú wọ̀nyí mọ́ àwọn ilẹ̀ tí ó kan Mozambique gbàngbàn. Àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mozambique tó 7,376,000. Púpọ̀ nínú wọn ni ó jẹ́ Bantu. Púpọ̀ nínú wọn ni ó ń ṣiṣẹ́ ní South Africa níbi tí wọ́n ti ń wa ohun àlùmọ́-ọ́nni ilẹ̀ (minerals). Àwọn mìíràn ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀. Wọ́n ń gbẹ òwú, kaṣú, ìrèké àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Orí ilẹ̀ pẹẹrẹ ni wọ́nm ti ń gbin àwọn wọ̀nyí. Orí òkè ni wọ́n tí ń gbin tíì (tea).
Vasco da Gama ni ó ṣe àwárí Mozambique ní 1498. Àwọn ara Portugal bẹ̀rẹ̀ síí wá sí ibẹ̀ ní nǹkan bí 1500. Mozambique sì bẹ̀rẹ̀ síí ṣe pàtàkì fún òwò ẹrú. Àwọn ilé-iṣẹ́ (companies) ni ó ń darí ilẹ̀ yìí láti 1891 sí 1942. Ọdún 1942 ni ìjọba Portugal bẹ̀rẹ̀ síí darí ilẹ̀ yìí. Ní 1960 àti 1970, Portugal kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun lọ sí Mozambique láti bá àwọn tí ó ń jà fún òmìnira jà.
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Department of Economic and Social Affairs Population Division (2009) (.PDF). World Population Prospects, Table A.1. 2008 revision. United Nations. http://www.un.org/esa/population/publications/wpp2008/wpp2008_text_tables.pdf. Retrieved 2009-03-12.
- ↑ 2.0 2.1 2.2 2.3 "Mozambique". International Monetary Fund. Retrieved 2009-10-01.